Elizabeth Ọmọ́wùnmí Tekovi Da-Silva (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀fà Ọjọ́ 10, Ọdún 1978) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Tógò tí ó maá n sábà kópa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nínu fíìmù Yorùbá ti Nàìjíríà. Ní ọdún 2016, wọ́n yan Da-Silva fún àmì ẹ̀yẹ City People Movie Award fún ti òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ (ẹ̀ka ti eré Yorùbá) níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards. Ní ọdún 2018 bákan náà, ó gba àmì ẹ̀yẹ fún òṣèré amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Best of Nollywood Awards.
© MMXXIII Rich X Search. We shall prevail. All rights reserved. Rich X Search